Dáníẹ́lì 7:24-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Ìwo mẹ́wàá ni ọba mẹ́wàá tí yóò wá láti inú ìjọba yìí. Lẹ́yìn tí wọn ní ọba mìíràn yóò díde, ti yóò yàtọ̀ sí tí àwọn ti ìṣáájú, yóò sì borí ọba mẹ́ta.

25. Yóò sọ̀rọ̀ odi sí ọ̀gá ògo, yóò sì pọ́n ẹni mímọ́ lójú, yóò sì gbèrò láti yí ìgbà àti òfin padà. A ó fi àwọn ẹni mímọ́ lé e lọ́wọ́ fún ìgbà díẹ̀, ní ọdún méjì àti ààbọ̀.

26. “ ‘Ṣùgbọ́n àwọn onídàájọ́ yóò jókòó, nígbà náà ni a ó gba agbára rẹ̀, a ó sì pa á rùn pátapáta títí ayé.

Dáníẹ́lì 7