15. Nígbà náà, ni àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọ̀nyí kó ara wọn jọ wá sí ọ̀dọ̀ ọba, wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ọba rántí pé, ní ìbámu pẹ̀lú òfin àwọn Médíà àti Páṣíà kò sí àṣẹ tàbí ìkéde tí ọba ṣe tí a le è yí i padà.”
16. Nígbà náà, ni ọba pàṣẹ, wọ́n sì mú Dáníẹ́lì, wọ́n sì sọ ọ́ sínú ihò kìnnìún. Ọba sì sọ fún Dáníẹ́lì pé, “Kí Ọlọ́run rẹ tí ìwọ ń sìn nígbà gbogbo kí ó gbà ọ́!”
17. A sì gbé òkúta kan wá, wọ́n sì fi dí ẹnu ihò náà, ọba sì dí i pa pẹ̀lú òrùka èdìdì rẹ̀ àti pẹ̀lú òrùka àwọn ọlọ́lá rẹ̀, nítorí kí a má ṣe yí ohunkóhun padà nítorí i Dáníẹ́lì.
18. Nígbà náà ni ọba padà sí ààfin rẹ̀, ó sì lo gbogbo òru náà láì jẹun, kò sì gbọ orin kankan, bẹ́ẹ̀ ni kò sì le è ṣùn ní òru ọjọ́ náà.
19. Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, ni ọba dìde ó sì sáré lọ sí ibi ihò kìnnìún náà.
20. Nígbà tí ó sún mọ́ ibi ihò náà ní ibi tí Dáníẹ́lì wà, ó pe Dáníẹ́lì pẹ̀lú ìtara pé, “Dáníẹ́lì, ìránṣẹ́ Ọlọ́run alààyè, ṣé Ọlọ́run rẹ tí ìwọ ń sìn tọ̀sán tòru, lè gbà ọ́ lọ́wọ́ ọ kìnnìún bí?”
21. Dáníẹ́lì sì dáhùn wí pé, “Ọba kí ẹ pẹ́!
22. Ọlọ́run mi rán ańgẹ́lì i rẹ̀, ó sì dí àwọn kìnnìún lẹ́nu. Wọn kò le è pamí lára, nítorí a rí mi gẹ́gẹ́ bí aláìlẹ́ṣẹ̀ ní iwájú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò hu ìwà ìbàjẹ́ kan níwájú rẹ ìwọ ọba.”
23. Inú ọba dùn gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a mú Dáníẹ́lì jáde wá láti inú ihò. Nígbà tí a mú Dáníẹ́lì jáde nínú ihò, kò sí ojú ọgbẹ́ kan ní ara rẹ̀, nítorí tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run rẹ̀.