Dáníẹ́lì 6:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó dára lójú Dáríúsì láti yan ọgọ́fà àwọn baálẹ̀ sórí ìjọba,

2. pẹ̀lú alákòóso mẹ́ta, Dáníẹ́lì sì jẹ́ ọ̀kan nínú un wọn, kí àwọn baálẹ̀ lè wá máa jẹ́ ààbọ̀ fún wọn, kí ọba má ba à ní ìpalára.

3. Dáníẹ́lì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ láàrin àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ nítorí ẹ̀mí tí ó tayọ wà lára rẹ̀ dé bi pé ọba sì ń gbérò láti fi ṣe olórí i gbogbo ìjọba.

Dáníẹ́lì 6