Dáníẹ́lì 5:27-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Tékélì: A ti gbé ọ lórí òṣùwọ̀n, ìwọ kò sì tó ìwọ̀n.

28. Pérésínì: A ti pín ìjọba rẹ a sì ti fi fún àwọn Médíà àti àwọn Páṣíà.”

29. Nígbà náà ni Beliṣáṣárì pàṣẹ pé kí a wọ Dáníẹ́lì ní aṣọ eléṣèé àlùkò, kí a sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn, a sì kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí kẹta ní ìjọba rẹ̀.

30. Ní alẹ́ ọjọ́ náà ni a pa Beliṣáṣárì, ọba Bábílónì.

31. Dáríúsì ará Médíánì sì gba ìjọba nígbà tí ó di ọmọ ọdún méjìlélọ́gọ́ta (62).

Dáníẹ́lì 5