Àwọn Hébérù 9:26-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Bí bẹ́ẹ̀ bá ni oun ìbá tí máa jìyà nígbàkúgbà láti ìpìlẹ̀ ayé: Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ni ó fi ara hàn lẹ́ẹ́kanṣoṣo lópìn ayé láti mi ẹ̀ṣẹ̀ kúrò nípa ẹbọ ara rẹ̀.

27. Níwọ̀n bí a sì ti fi lélẹ̀ fún gbogbo ènìyàn láti kú lẹ̀ẹ̀kanṣoṣo, ṣùgbọ́n lẹ̀yìn èyí ìdájọ́:

28. Bẹ́ẹ̀ ni Kírísítì pẹ̀lú lẹ̀yìn tí a ti fi rúbọ lẹ̀ẹ̀kanṣoṣo láti ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, yóò farahàn ní ìgbà kéjì láìsí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí n wo ọ̀nà rẹ̀ fún ìgbàlà.

Àwọn Hébérù 9