Àwọn Hébérù 6:18-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Pé, nípa ohun àìlèyípadà méjì, nínú èyí tí kò le ṣe é ṣe fún Ọlọ́run láti ṣèké, kí a lè mú àwa tí ó ti sá sábẹ́ ààbò rẹ̀ ní ọkàn lè láti di ìrètí tí a gbé kalẹ̀ níwájú wa mú sinsin:

19. Èyí tí àwa ní bi ìdákọ̀ró ọkàn fún ọkàn wa, ìrètí tí ó dájú tí ó sì dúró ṣinṣin, tí ó sì wọ inú ilé lọ lẹ̀yìn aṣọ ìkélé;

20. Níbi tí Jésù, aṣáájú wa ti wọ̀ lọ fún wa, òun sì ni a fi jẹ Olórí àlùfáà títí láé nípasẹ̀ Melekisédékì.

Àwọn Hébérù 6