20. Nítorí pé ara wọn kò lè gba ohun tí ó palaṣẹ, “Bí o tilẹ̀ jẹ ẹranko ni o farakan òkè náà, a o sọ ọ ni òkúta, tàbí a o gun un ní ọ̀kọ̀ pa.”
21. Ìran náà sì lẹ̀rù to bẹ́ẹ̀ tí Móṣè wí pé, “Ẹrù ba mi gidigidi mo sì wárìrì.”
22. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wá sí òkè Síónì, àti sí ìlú Ọlọ́run alààyè, ti Jerúsálémù ti ọ̀run, àti si ẹgbẹ́ àwọn áńgẹ́lì àìníye,
23. Si àjọ ńlá tí ìjọ àkọ́bí tí a ti kọ orúkọ wọn ni ọ̀run, àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run onídájọ́ gbogbo ènìyàn, àti sọ́dọ̀ àwọn ẹ̀mí olóòtọ́ ènìyàn tí a ṣe ni àṣepé, o
24. Àti sọ́dọ̀ Jésù alárinà májẹ̀mú titun, àti si ibi ẹ̀jẹ̀ ìbùwọ́n ni, ti ń sọ̀rọ̀ ohun tí ó dára ju ti Ábélì lọ.