Àwọn Hébérù 11:12-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Nítorí náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣe ti ara ọkùnrin kan jáde, àní ara ẹni tí o dàbí òkú, ọmọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ́pọ̀lọpọ̀, àti bí ìyanrìn etí òkun láìníyè.

13. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni o kú ní ìgbàgbọ́, láì rí àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n tí wọn rí wọn ni òkèrè réré, ti wọn si gbá wọn mú, tí wọn sì jẹ̀wọ́ pé àlejò àti àtìpó ni àwọn lórí ilẹ́ ayé.

14. Nítorí pé àwọn tí o ń ṣọ irú ohun bẹ́ẹ̀ fihàn gbangba pé, wọn ń ṣe àfẹ́rí ìlú kan tí i ṣe tiwọn.

15. Àti ní tòótọ́, ìbáṣe pé wọn fi ìlú ti wọn tí jáde wá sí ọkàn, wọn ìbá ti rí àyè padà.

Àwọn Hébérù 11