Ámósì 5:23-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ẹ gbé ariwo orin yín sẹ́yìnÈmi kò ní fetísí ohun èlò orin yín.

24. Jẹ́ kí òtítọ́ ṣàn bí odòàti òdodo bí ìsun tí kò lé è gbẹ

25. “Àbí ẹ̀yin mú ẹbọ àti ọrẹ tọ̀ mí wání ogójì ọdún ní ihà ìwọ ilé Ísírẹ́lì?

26. Ẹ̀yin ń gbé ibi ìrúbọ àwọn ọba yínibùgbé àwọn òrìṣà yínàní, ti àwọn òrìṣà yín tí ó níyì jùlọ,èyí tí ẹ̀yin fi ọwọ́ ara yín ṣe.

27. Nítorí náà èmi yóò rán an yín lọ sí ìgbèkùn ní ìkọjá Dámásíkù,”ni Olúwa wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọ́run alágbára.

Ámósì 5