1. Olúwa sọ fún mi pé, mú ìwé ńlá kan, kí o sì fi pẹ́ẹ́nì lásán kọ Maha-Ṣalali-Haṣi-Baṣì:
2. Èmi yóò sì pe Hùráyà, Àlùfáà àti Ṣekaráyà ọmọ Jébérékíà gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí tí ó ṣeé gbọ́kànlé fún mi.
3. Lẹ́yìn náà, mo lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì-obìnrin náà, ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Olúwa sì wí fún mi pé, “pe orúkọ rẹ̀ ní Maha-Ṣalali-Haṣi-Baṣì.
4. Kí ọmọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń sọ pé ‘Baba mi’ tàbí ‘Ìyá mi’ gbogbo ọrọ̀ Dámásíkù àti ìkógun ti Ṣamáríà ni ọba àwọn Áṣíríà yóò ti kó lọ.”