Àìsáyà 7:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ṣíbẹ̀ èyí ni ohun tí Olúwa Àwọn ọmọ ogun wí:“ ‘Èyí kò ní wáyéÈyí kò le ṣẹlẹ̀,

8. nítorí Dámásíkù ni orí Árámù,orí Dámásíkù sì ni Résínì.Láàrin ọdún márùnlélọ́gọ́taÉfáímù yóò ti fọ́ tí kì yóò le jẹ́ ènìyàn mọ́.

9. Ṣamaríà ni orí fún Éfáímù,ẹni tí ó sì jẹ́ orí Samaríà náà ni ọmọ Rèmálíà.’ ”

10. Bákan náà Olúwa tún bá Áhásì sọ̀rọ̀,

Àìsáyà 7