9. A ó mọ ìrandíran wọn láàrin àwọn orílẹ̀ èdèàti àwọn ìran wọn láàrin àwọn ènìyànGbogbo àwọn tí ó bá rí wọn yóò mọ̀ péwọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí Olúwa ti bùkún.”
10. Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa;ọkàn mi yọ̀ nínú Ọlọ́run mi.Nítorí ó ti wọ̀ mí ní aṣọ ìgbàlàó sì ṣe mí lọ́ṣọ̀ọ́ nínú aṣọ òdodo;gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ti ṣe oríi rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ bí àlùfáà,àti bí ìyàwó ṣe ń ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́.
11. Gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ti í mú èhù jádeàti bí ọgbà ṣe ń mú irúgbìn dàgbà,Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò ṣe mú òdodo àti ìyìnkí ó ru sókè níwájú gbogbo orílẹ̀ èdè.