Àìsáyà 57:12-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Èmi yóò sí òdodo yín payá àti iṣẹ́ẹ yín,wọn kì yóò sì ṣe yín ní àǹfààní.

13. Nígbà tí ẹ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́ẹ jẹ́ kí àkójọ àwọn ère yín gbà yín!Atẹ́gùn yóò gbá gbogbo wọn lọ,èémí lásán làsàn ni yóò gbá wọn lọ.Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi mí ṣe ààbò rẹ̀ni yóò jogún ilẹ̀ náàyóò sì jogún òkè mímọ́ mi.”

14. A ó sì sọ wí pé:“Tún mọ, tún mọ, tún ọ̀nà náà ṣe!Ẹ mú àwọn ohun ìkọ̀ṣẹ̀ kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi.”

Àìsáyà 57