23. Nípa èmi tìkálára mi ni mo ti búra,ẹnu mi ni ó ti sọ ọ́ pẹ̀lúu gbogbo ipá miọ̀rọ̀ náà tí a kì yóò lè parẹ́:Níwájú mi ni gbogbo orúnkún yóò wólẹ̀;nípa mi ni gbogbo ahọ́n yóò búra.
24. Wọn yóò sọ ní ti èmi, ‘Nínú Olúwa nìkan niòdodo àti agbára wà.’ ”Gbogbo àwọn tí ó ti bínú sí;yóò wá sọ́dọ̀ rẹ̀ a ó sì dójú tì wọn.
25. Ṣùgbọ́n nínú Olúwa gbogbo àwọn ìran Ísírẹ́lìni a ó rí ní òdodo, a o sì gbé wọn ga.