Àìsáyà 45:16-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Gbogbo àwọn tí ó ń gbẹ́ ère ni ojú yóò tìwọn yóò sì kan àbùkù;gbogbo wọn ni yóò bọ́ sínú àbùkù papọ̀.

17. Ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì ni a ó gbàlà láti ọwọ́ OlúwaPẹ̀lú ìgbàlà ayérayé;a kì yóò kàn yín lábùkù tàbí kí a dójú tì yín,títí ayé àìnípẹ̀kun.

18. Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí—ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run,Òun ni Ọlọ́run;ẹni tí ó mọ tí ó sì dá ayé,Òun ló ṣe é;Òun kò dá a láti wà lófo,ṣùgbọ́n ó ṣe é kí a lè máa gbé ibẹ̀—Òun wí pé:“Èmi ni Olúwa,kò sì sí ẹlòmìíràn.

Àìsáyà 45