Àìsáyà 32:11-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Wárìrì, ẹ̀yin obìnrin onítẹ̀lọ́rùnbẹ̀rù, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ẹ rò pé ọkàn yín balẹ̀!Ẹ bọ́ aṣọ yín kúrò,ẹ ró aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ẹ yín.

12. Ẹ lu ọmú un yín fún pápá ìgbádùn náà,fún àwọn àjàrà eléso

13. àti fún ilẹ̀ àwọn ènìyàn miilẹ̀ tí ó ti kún fún ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n—bẹ́ẹ̀ ni, kẹ́dùn fún gbogbo ilé ìturaàti fún ìlú àríyá yìí.

14. Ilé olódi ni a ó kọ̀ sílẹ̀,ìlù aláriwo ni a ó kọ̀tì;ilé olódi àti ilé ìṣọ́ ni yóò di ìdànù títí láéláé,ìdùnnú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti pápáoko fún àwọn ẹran ọ̀sìn,

15. títí a ó fi tú Ẹ̀mí sí wa lórí láti òkè wá,àti ti aṣálẹ̀ tí yóò dí pápá oko ọlọ́ràáàti tí pápá ọlọ́ràá yóò dàbí ẹgàn.

16. Ẹ̀tọ́ yóò máa gbé ní inú aṣálẹ̀àti òdodo yóò sì máa gbé ní pápá oko ọlọ́ràá.

Àìsáyà 32