23. Òun yóò sì rọ òjò fún un yín sí àwọn irúgbìn tí ẹ gbìn sórí ilẹ̀, oúnjẹ tí yóò ti ilẹ̀ náà wá yóò ní ọ̀rá yóò sì pọ̀. Ní ọjọ́ náà ni àwọn ẹran ọ̀sìn yín yóò máa jẹ koríko ní pápá oko tútù tí ó tẹ́jú.
24. Àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ń tú ilẹ̀ yóò jẹ oúnjẹ àdídùn tí a fi amúga àti ṣọ́bìrì fọ́nkálẹ̀.
25. Ní ọjọ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò sọ ẹ̀míi wọn nù nígbà tí ilé ìṣọ́ yóò wó lulẹ̀, odò omi yóò ṣàn lórí òkè gíga àti lórí àwọn òkè kékeré.