12. Ní ọjọ́ náà Olúwa yóò sì kó ooré láti ìṣàn omi Éúfírétì wá títí dé Wádì ti Éjíbítì, àti ìwọ, ìwọ ọmọ Ísírẹ́lì, ni a ó kójọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.
13. Àti ní ọjọ́ náà, a ó fun fèrè ńlá kan. Gbogbo àwọn tí ń ṣègbé lọ ní Ásíríà àti àwọn tí ń ṣe àtìpó ní Éjíbítì yóò wá sin Olúwa ní òkè mímọ́ ní Jérúsálẹ́mù.