8. ‘Kì í haá ṣe pé ọba ni gbogbo àwọn aláṣẹ mi?’ ni Olúwa wí.
9. ‘Kì í ha á ṣe pé Kálínò dàbí i Káṣẹ́míṣì?Hámátì kò ha dàbí i Ápádì,àti Ṣamáríà bí i Dámásíkù?
10. Gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ti gbá ìjọba àwọn òrìṣà mú,Ìjọba tí ère rẹ̀ pọ̀ ju ti Jérúsálẹ́mù àti Ṣamáríà lọ.
11. Èmi kì yóò a bá Jérúsálẹ́mù wí àti àwọn ère rẹ̀?’ ”Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe sí Ṣamáría àti àwọn ère rẹ̀?
12. Nígbà tí Olúwa bá parí iṣẹ́ rẹ̀ sí òkè Ṣíhónì àti Jérúsálẹ́mù, yóò sọ wí pé, “Èmi yóò fi ìyà jẹ Ásíríà nítoríi gààrù àyà rẹ̀ àti ìgbéraga ojúu rẹ̀.
13. Nítorí ó sọ pé:“ ‘Pẹ̀lú agbára ọwọ́ọ̀ mi ni mo fi ṣe èyíàti pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀n mi, nítorí mo ní òye.Mo mú ààlà àwọn orílẹ̀ èdè kúrò,Mo sì ti kó ìṣúra wọn.Gẹ́gẹ́ bí alágbára kan, mo borí àwọn ọba wọn.