2 Tímótíù 2:23-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ìbéèrè òmùgọ̀ àti aláìní èkọ́ nínú ni kí a kọ̀, bí a ti mọ̀ pe wọn a máa dá ìjà sílẹ̀.

24. Ìránsẹ́, Olúwa kò sì gbọdọ̀ jà; bí kò ṣe kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí ènìyàn gbogbo ẹni tí ó lè kọ́ni, onísùúrù.

25. Ẹni tí yóò máa kọ́ àwọn alátakò pẹ̀lú ìwà tútù, ní ìrèti pé Ọlọ́run lè fún wọn ní ìrònúpìwàdà sí ìmọ̀ òtìtọ́,

26. wọn ó sì lè bọ́ kúrò nínú ìdèkùn èṣù, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti mú wọn láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

2 Tímótíù 2