2 Tímótíù 1:14-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Pa ohun rere ti a ti fi lé ọ lọ́wọ́ mọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ ti ń gbé inú wa.

15. Èyí ni ìwọ mọ̀ pé, gbogbo àwọn ti ó wà ni agbègbè Ésíà ti fí mí sílẹ̀, nínú àwọn ẹni tí Fígélíù àti Hámógénè gbé wà.

16. Kí Olúwa fi àánú fún ilé Ònésífórù; nítorí ti ó máa ń tù mi lára nígbà púpọ̀, ẹ̀wọ̀n mi kò sì tì í lójú.

17. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wà ni Rómù, ó fi ẹ̀sọ̀ wá mi, ó sì rí mi.

18. Kí Olúwa fi fún un kí ó lè rí àánú lọ́dọ̀ Olúwa ni ọjọ́ náà! Ìwọ tìkararẹ sáà mọ̀ ọ̀nà gbogbo tí ó gbà rànmí lọ́wọ́ ni Éfésù.

2 Tímótíù 1