2 Tẹsalóníkà 3:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní àkótan, ará, ẹ máa gbàdúrà fún wa, kí ọ̀rọ̀ Olúwa lè máa tàn káàkiri, kí ó sì jẹ́ èyí tí a bu ọlá fún, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọ̀dọ̀ yín.

2. Kí ẹ sì máa gbàdúrà fún wa kí a lè bọ lọ́wọ́ àwọn ìkà àti àwọn ènìyàn búburú, nítorí pé kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló ní ìgbàgbọ́.

3. Ṣùgbọ́n olódodo ni Olúwa, ẹni tí yóò fi ẹ̀ṣẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóò sì pa yín mọ́ kúrò nínú ibi.

2 Tẹsalóníkà 3