1. Dáfídì sì tún kó gbogbo àwọn akọni ọkùnrin ní Ísírẹ́lì jọ, wọ́n sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀dógún.
2. Dáfídì sì dìde, ó sì lọ àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ́ lọ́dọ̀ rẹ́, láti Báálà Júdà wá, láti mú àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run tí ibẹ̀ wá, èyí tí a ń pe orúkọ rẹ̀ ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó jókòó láàrin àwọn kérúbù.
3. Wọ́n sì gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run náà gun kẹ̀kẹ́ tuntun kan, wọ́n sì mú un láti ilé Ábínádábù wá, èyí tí ó wà ní Gíbéà: Úsà àti Áhíò, àwọn ọmọ Ábínádábù sì ń dá kẹ̀kẹ́ tuntun náà.
4. Wọ́n sì mú un láti ilé Ábínádábù jáde wá, tí ó wà ní Gíbéà, pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run: Áhíò sì ń rìn níwájú àpótí-ẹ̀rí náà.