2 Sámúẹ́lì 24:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Dáfídì sì wí fún Olúwa nígbà tí ó rí ańgẹ́li tí ń kọlu àwọn ènìyàn pé, “Wò ó, èmi ti ṣẹ̀, èmi sì ti hùwà búburú ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn wọ̀nyí, kín ni wọ́n ha ṣe? Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, kí ó wà lára mi àti ìdílé baba mi.”

18. Gádì sì tọ Dáfídì wá lọ́jọ́ náà, ó sì wí fún un pé, “Gòkè, tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa níbi ìpakà Áráúnà ará Jébúsì.”

19. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Gádì, Dáfídì sì gòkè lọ bí Olúwa ti pa á láṣẹ.

2 Sámúẹ́lì 24