8. Támárì sì lọ sí ilé Ámúnónì ẹ̀gbọ́n rẹ̀, òun sì ń bẹ ní ìdúbúlẹ̀. Támárì sì mú ìyẹ̀fun, ó sì pò ó, ó sì fi ṣe àkàrà lójú rẹ̀, ó sì dín àkàrà náà.
9. Òun sì mú àwo náà, ó sì dà á sínú àwo mìíràn níwájú rẹ̀; ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti jẹ.Ámúnónì sì wí pé, “Jẹ́ kí gbogbo ọkùnrin jáde kúrò lọ́dọ̀ mi!” Wọ́n sì jáde olúkúlùkù ọkùnrin kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
10. Ámúnónì sì wí fún Támárì pé, “Mú oúnjẹ náà wá sí yàrá, èmi ó sì jẹ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ.” Támárì sì mú àkàrà tí ó ṣe, ó sì mú un tọ Ámúnónì ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní yàrá.
11. Nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti fi oúnjẹ fún un, òun sì dì í mú, ó sì wí fún un pé, “Wá dùbúlẹ̀ tì mí, àbúrò mi.”
12. Òun sì dá a lóhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀gbọ́n mi, má ṣe tẹ́ mi; nítorí pé kò tọ kí a ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ní Ísírẹ́lì, ìwọ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí.
13. Àti èmi, níbo ni èmi ó gbé ìtìjú mi wọ̀? Ìwọ ó sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn aṣiwèrè ní Ísírẹ́lì. Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́, sọ fún ọba; nítorí pé òun kì yóò kọ̀ láti fi mí fún ọ.”