24. Ábúsálómù sì tọ ọba wá, ó sì wí pé, “Wò ó, jọ̀wọ́, ìránṣẹ́ rẹ ní olùrẹ́run àgùntàn, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ọba, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ìránṣẹ́ rẹ lọ.”
25. Ọba sì wí fún Ábúsálómù pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí gbogbo wa lọ, kí a má báà mú ọ náwó púpọ̀.” Ó sì rọ̀ ọ́ gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ lọ, òun sì súre fún un.
26. Ábúsálómù sì wí pé, “Bí kò bá le rí bẹ́ ẹ̀, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí Ámúnónì ẹ̀gbọ́n mi bá wa lọ.”Ọba sì wí pé, “Ìdí rẹ̀ tí yóò fi bá ọ lọ.”
27. Ábúsálómù sì rọ̀ ọ́, òun sì jẹ́ kí Ámúnónì àti gbogbo àwọn ọmọ ọba bá a lọ.
28. Ábúsálómù sì fi àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Kí ẹ̀yin máa kíyèsí àkókò tí ọtí-wáinì yóò mú ọkàn Ámúnónì dùn, èmi ó sì wí fún yín pé, ‘Kọlu Ámúnónì,’ kí ẹ sì pa á. Ẹ má bẹ̀rù. Ṣé èmi ni ó fi àṣẹ fún yin? Ẹ ṣe gírí, kí ẹ ṣe bí alágbára ọmọ.”
29. Àwọn ìránṣẹ́ Ábúsálómù sì ṣe sí Ámúnónì gẹ́gẹ́ bí Ábúsálómù ti páṣẹ. Gbogbo àwọn ọmọ ọba sì dìde, olúkúlukú gun ìbaka rẹ̀, wọ́n sì sá.