3. Dáfídì sì béèrè pé, “Ibo ni ìwọ ti wá?”“Èmi sá láti ibùdó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”
4. Dáfídì béèrè pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀?” “Sọ fún mi.”Ó wí pé, “Àwọn ọkùnrin náà sá láti ojú ogun. Ọ̀pọ̀ wọn ṣubú, wọ́n sì kú. Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Jónátanì sì kú pẹ̀lú.”
5. Nígbà náà, ní Dáfídì sọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún un pé, “Báwo ni o ṣe mọ̀ pé Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọkùnrin rẹ̀ Jónátanì ti kú.”
6. “Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sọ pé, mo wà ní orí òkè Gílíbóà níbẹ̀ ni Ṣọ́ọ̀lù fi ara tí ọkọ̀ rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin sì ń lépa rẹ̀.
7. Nígbà tí ó wò yíká, tí ó rí mí, ó pè mi, mo sì wí pé, kí ni mo lè ṣe?
8. “Ó bi mí wí pé, ‘Ta ni ìwọ?’“Mo dáhùn pé, ‘Ará a Ámálékì,’