29. (Ní ọdún kọkànlá ti Jórámù ọmọ Áhábù, Áhásáyà ti di ọba Júdà.)
30. Nígbà náà Jéhù lọ sí Jésérẹ́lì. Nígbà tí Jésébélì gbọ́ nípa rẹ̀, ó kun ojú u rẹ̀, ó to irun rẹ̀, ó sì wò jáde láti ojú fèrèsé.
31. Bí Jéhù ti wọ ẹnu ìlẹ̀kùn, ó béèrè, “Ṣé ìwọ wá lálàáfíà, Símírì, ìwọ olùpa ọ̀gá à rẹ?”
32. Ó gbójú sókè láti wo fèrèsé, ó sì pè jáde, “Ta ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ mi? Ta ni?” Ìwẹ̀fà méjì tàbí mẹ́ta bojú wò ó nílẹ̀.
33. Jéhù sọ wí pé, “Gbé e jùsílẹ̀ wọ́n sì jù ú sílẹ̀!” Díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì fọ́n sí ara ògiri àti àwọn ẹṣin bí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ wọn.
34. Jéhù wọ inú ilé lọ, ó jẹ ó sì mu. “Tọ́jú obìnrin yẹn tí a fi bú,” Ó wí, “Kí o sì sin-ín, nítorí ọmọbìnrin ọba ni ó jẹ́.”
35. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n jáde lọ láti lọ sin-ín, wọn kò rí nǹkankan àyàfi agbárí i rẹ̀, ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì àti ọwọ́ ọ rẹ̀ méjèèjì.