1. Nígbà tí ó di ọdún kẹsàn án ìjọba Ṣédékíàyà. Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹwàá, Nebukadinésárì ọba Bábílónì yan lọ sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú gbogbo àwọn ogun rẹ̀. Ó sì pàgọ́ sí ìta ìlú ó sì mu àwọn isẹ ìdọ̀tì fi yí gbogbo rẹ̀ ká.
2. Ìlú náà sì wà ní ìhámọ́ lábẹ́ ìdọ̀tí títí di ọdún kọkànlá ti ọba Ṣédékíáyà.
3. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹrin, iyàn tí mú ní ìlú tí ó jẹ́ wí pé kò sí oúnjẹ fún àwọn ènìyàn láti jẹ.