Jéhóáhásì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́talélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún oṣù mẹ́ta. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Hámútalì ọmọbìnrin Jeremíáyà; ó wá láti Líbínánì.