24. Mo ti gbẹ́ kàǹga ní ilẹ̀ àjèjìMo sì mu omi níbẹ̀.Pẹ̀lú àtẹ́lẹṣẹ̀ mi,Èmi ti gbẹ́ gbogbo omi odò tí ó wà ní Éjíbítì.”
25. “ ‘Ṣé ìwọ kò tí ì gbọ́?Ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn mo yàn án.Ní ọjọ́ ogbó ni mo ṣètò rẹ̀;nísinsìn yìí mo ti mú wá sí ìkọjápé ìwọ ti yí ìlú olódi padà díòkítì àlàpà òkúta.
26. Àwọn ènìyàn wọn ń gbẹ nípa,wọ́n ti dàá láàmúwọ́n sì ti sọọ́ di ìtìjú.Wọ́n dà bí koríko ìgbẹ́ lórí pápá,gẹ́gẹ́ bí ọkà tí ó rẹ̀ dànù kí ó tó dàgbà sókè,gẹ́gẹ́ bí fífún ọkà tí ó hù jáde.
27. “ ‘Ṣùgbọ́n èmi mọ ibi tí ìwọdúró àti ìgbà tí ìwọ bá dé tàbílọ àti bí ìwọ ṣe ikáanú rẹ: sí mi.
28. Ṣùgbọ́n ikáanú rẹ sí mi àti ìrora rẹ dé etí mi,Èmi yóò gbé ìwọ̀ mi sí imúrẹ àti ìjánú mi sí ẹnu rẹ,èmi yóò mú ọ padà nípa wíwá rẹ’