2 Ọba 18:26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)
Nígbà náà Éláékímù ọmọ Hílíkíáyà, àti ṣébínà àti Jóà sọ fún olùdarí pápá pé, “Jọ̀wọ́ sọ̀rọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ ní èdè Ṣíríà, nítorí ti ó tí yé wa, má ṣe sọ̀rọ̀ fún wa pẹ̀lú èdè Hébérù ní etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn tí ń bẹ lórí odi.”