2 Ọba 13:20-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Èlíṣà kú a sì sin ín.Ẹgbẹ́ Àwọn ará Móábù máa ń wọ orílẹ̀ èdè ní gbogbo àmọ́dún.

21. Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ti ń sin òkú ọkùnrin kan, lójijì wọ́n rí ẹgbẹ́ àwọn oníjadì: Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ju òkú ọkùnrin náà sínú ibojì Èlíṣà. Nígbà tí ara ọkùnrin náà kan egungun Èlíṣà, ó padà wá sí ayé, ó sì dúró ní ẹsẹ̀ rẹ̀.

22. Hásáélì ọba Ṣíríà ni Ísírẹ́lì lára ní gbogbo àkókò tí Jéhóáhásì fi jọba.

23. Ṣùgbọ́n Olúwa ṣàánú fún wọn ó sì ní ìyọ́nú, ó sì fiyèsí wọn nítorí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù, Ísákì àti Jákọ́bù. Títí di ọjọ́ òní, kì í ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ láti pa wọ́n run tàbí lé wọn lọ níwájú rẹ̀.

2 Ọba 13