1. Lẹ́yìn ikú Áhábù, Móábù sọ̀tẹ̀ sí Ísírẹ́lì.
2. Nísinsìn yìí Áhásáyà ti ṣubú láàrin fèrèsé láti òkè yàrá rẹ̀ tí ó wà ní Ṣamáríà, ó sì fi ara pa. Ó sì rán oníṣẹ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Bálísébúbù, òrìṣà Ékírónì, bóyá èmi ó lè rí ìwòsàn ìfarapa yìí.”
3. Ṣùgbọ́n ańgẹ́lì Olúwa wí fún Èlíjà ará Tíṣíbì pé, “Lọ sókè kí o lọ bá ìránṣẹ́ ọba Ṣámáríà kí o sì bèèrè lọ́wọ́ wọn, ‘Ṣé nítorí pé kò sí Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì ni ẹ̀yìn fi jáde lọ ṣèwádìí lọ́wọ́ Bálísébúbù òrìṣà Ékírónì?’
4. Nítorí náà ohun tí Olúwa sọ ni èyí: ‘Ìwọ kò ní kúrò lórí ìbùsùn tí o dúbúlẹ̀ lé. Dájúdájú ìwọ yóò kú!’ ” Bẹ́ẹ̀ ni Èlíjà lọ.