2 Kọ́ríńtì 12:20-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé, nígbà tí mo bá dé, èmi kì yóò bá yín gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí mo fẹ́, àti pé ẹ̀yin yóò sì rí mi gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí ẹ̀yin kò fẹ́: Kí ìjà, owú-jíjẹ, ìbínú, ìpínyà, ìsọ̀rọ̀-ẹni-lẹ́yìn, ìjírọ̀sọ̀, ìfẹẹ́gẹ̀, ìrúkèrúdò, má bà à wà.

21. Àti nígbà tí mo bá sì padà dé, kí Ọlọ́run mí má bà à rẹ̀ mí sílẹ̀ lójú yín, àti kí èmi má bà à sọkún nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó tí ṣẹ̀ náà tí kò sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ ìwà èérí, àgbérè, àti wọ̀bìà tí wọ́n ti hù.

2 Kọ́ríńtì 12