2 Kíróníkà 5:1 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)
Nígbà tí gbogbo iṣẹ́ tí Sólómónì ti ṣe fún tẹ́ḿpìlì ti parí, ó kó gbogbo àwọn nǹkan tí Dáfìdì baba rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀: wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun èlò ọ̀sọ́, ó sì fi wọ́n sínú ìsúra ilé Ọlọ́run.