1. Nígbà náà gbogbo ènìyàn Júdà mú Ùsáyà, ẹni tí ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún (16) wọ́n sì fi jẹ ọba ní ipò baba rẹ̀ Ámásíà.
2. Òun ni ẹni náà tí ó tún Élótù kọ́, ó sì mú padà sí Júdà Lẹ́yìn ìgbà tí Ámásíà ti sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀.
3. Ùsáyà sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjìléláadọ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jekolíà; ó sì wá láti Jérúsálẹ́mù.