2 Kíróníkà 25:18-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ṣùgbọ́n Jéhóáṣì ọba Ísírẹ́lì fèsì padà sí Ámásíà ọba Júdà pé, “Òṣùṣù kan ní Lẹ́bánónì rán isẹ́ sí òpépé (igi) ní Lẹ́bánónì, fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi ní ìgbéyàwo. Nígbà náà, ẹhànnà ẹranko ènìyàn ni Lébánónì wá, ó sì tẹ òṣùṣù náà lábẹ́ ẹsẹ̀.

19. Ìwọ wí fún ara à rẹ wí pé, ìwọ ti ṣẹ́gun Édómù àti nísinsin yìí ìwọ ní ìrera àti ìgbéraga. Ṣùgbọ́n dúró ní ilé! Kí ni ó dé tí o fi n wá wàhálà tí o sì fi ń fa ìṣubú rẹ àti ti Júdà pẹ̀lu?”

20. Ámásíà, bí ó tì wù kí ó rí kò ní tẹ́tí nítorí Ọlọ́run ṣe é kí ó lè gbé wọn lé Jéhóásì lọ́wọ́: nítorí wọ́n wá àwọn ọlọ́run Édómù.

21. Bẹ́ẹ̀ ni Jóásì, ọba Ísírẹ́lì: òun àti Ámásíà ọba Júdà dojúkọ ara wọn ní Bẹti Ṣeméṣì ní Júdà.

22. Àwọn ọmọ Ísirẹ́lì da Júdà rú, gbogbo olúkúlùkù ènìyàn sì sálọ sí ìlú rẹ̀.

23. Jóásì ọba Ísírẹ́lì fi agbára mú Áhásáyà ọba Júdà, ọmọ Jóáṣì ọmọ Áhásáyà ní Bétì Ṣéméṣì. Nígbà náà Jóásì mú u wá sí Jérúsálẹ́mù. Ó sì wó ògiri Jérúsálẹ́mù lulẹ̀ láti ẹnu ọ̀nà Éfíráímù sí igun ẹnu ọ̀nà apá kan títí ń lọ sí ọgọ́rùnún mẹ́fà ẹsẹ̀ bàtà ní gígùn.

2 Kíróníkà 25