15. Ṣùgbọ́n Jéhóiádà di arúgbó, ó sì kún fún ọjọ́, ó sì kú, ẹni àádóje ọdún ni nígbà tí ó kú.
16. Wọ́n sì sin ín ní ìlú Dáfídì pẹ̀lú àwọn ọba, nítorí tí ó ṣe rere ní Ísírẹ́lì, àti sí Ọlọ́run àti sí ilé rẹ̀.
17. Lẹ́yìn ikú Jéhóíadà, àwọn onisẹ́ Júdà wá láti fi ìforíbalẹ̀ wọn hàn sí ọba. Ó sì fèsì sí wọn.
18. Wọ́n pa ilé Olúwa tì, Ọlọ́run baba a wọn. Wọ́n sì ń sin àwọn òpó Áṣérà àti àwọn òrìṣà. Nítorí ẹbí wọn, ìbínu Ọlọ́run dé sórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù.
19. Bí ó ti wù kí ó rí, Olúwa rán àwọn wòlíì sí àwọn ènìyàn láti mú wọn padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, wọ́n jẹ́rìí nípa wọn, wọn kì yóò gbọ́.
20. Nígbà náà, ẹ̀mí Ọlọ́run wá sórí Ṣákáríhà ọmọ Jéhóíádà wòlíì, ó dúró níwájú àwọn ènìyàn ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Kí ni ó dé tí ẹ̀yin kò fi tẹ̀lé àṣẹ Olúwa? Ìwọ kì yóò ṣe rere. Nítorí tí ìwọ ti kọ Olúwa sílẹ̀, òun pẹ̀lú ti kọ̀ yín sílẹ̀.’ ”
21. Ṣùgbọ́n wọ́n dìtẹ̀ sí i, àti nípa àṣẹ ọba, wọ́n sọ ọ́ lókúta pa nínú àgbàlá ààfin ilé Olúwa