“Ámáríyà àlùfáà ni yóò jẹ́ olórí yín nínú gbogbo ọ̀ràn tí ó jẹ́ ti Olúwa, àti Ṣébádíà ọmọ Íṣímáélì alákòóso ìdílé Júdà, ní yóò jẹ́ olórí ní gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba, àti àwọn ará Léfì pẹ̀lu yin yóò sìn gẹ́gẹ́ bí ìjòyè níwájú yín. Ẹ ṣeé pẹ̀lú ìmọ́kànle, Olúwa yóò sì wà pẹ̀lú àwọn tó bá ń ṣe rere.”