1. Ní ọdún kẹrìndínlógójì ìjọba Ásà, Básà ọba Ísírẹ́lì gòkè wá sí Júdà ó sì kọlu Rámà, láti ma bàá jẹ́ kí ẹnikẹ́ni lè jáde tàbí wọlé tọ Ásà ọba Júdà lọ.
2. Nígbà náà ni Ásà mú wúrà àti fàdákà jáde ninú ilé ìsúra ilé Olúwa àti ààfin ọba ó sì ránsẹ́ sí Bẹni-Hádádì ọba Árámù, ẹni tí ń gbé ní Dámásíkù, ó wí pé,
3. “Májẹ̀mu kan wà láàrin èmi àti ìrẹ, bí ó ti wà láàrin baba mi àti baba rẹ. Ẹ wò ó, mo fi wúrà àti fàdákà ránsẹ́ sí ọ; lọ, ba májẹ̀mu tí o bá Básà ọba Ísirẹ́lì dá jẹ́, kí ó lè lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ mi”
4. Bẹni-hádádì sì gbọ́ ti Ásà ọba, ó sì rán àwọn olórí ogun rẹ̀ lọ sí àwọn ìlú Ísírẹ́lì, wọ́n sì kọlu Íjónì, Dánì, Abeli-Máímù, àti gbogbo ilú ìsúra Náfítalì.
5. Nígbà tí Básà gbọ́ èyi, ó sì dá kíkọ́ Rámà dúró, ó sì dá iṣẹ́ rẹ̀ dúró.
6. Nígbà náà ní ọba Ásà kó gbogbo àwọn ènìyàn Júdà jọ, wọ́n sì kó òkúta àti igi Rámà lọ èyí ti Básà ń fi kọ́lé; ó sì fi kọ́ Gébà àti Mísípà.