2 Kíróníkà 15:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Wọ́n péjọ sí Jérúsálẹ́mù ní oṣù kẹta ọdún kẹẹ̀dógún ti ìjọba Ásà.

11. Ní àkókò yìí, wọ́n rúbọ sí Olúwa ọgọ́rùnún méje akọ màlúù àti ẹgbẹ̀rún ḿéje (7,000) àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́ láti ibi ìkogun tí wọ́n ti kó padà.

12. Wọ́n sì tún dá májẹ̀mú láti wá Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn tinútinú wọn àti tọkàntọkàn wọn.

13. Pé ẹnikẹ́ni tí kò bá wá Olúwa Ọlọ́run Isirẹ́lì, pípa ni á ó paá láti ẹni kékeré dé orí ẹni ńlá àti ọkùnrin àti obìnrin.

2 Kíróníkà 15