13. Ọba sì dá wọn lóhùn ní ọ̀nà líle. Ó kọ̀ ìmọ̀ràn àwọn àgbààgbà,
14. Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọ̀dọ́mọdé, ó sì wí pé, “Baba mi mú kí àjàgà yín wúwo; Èmi yóò sì mú kí ó wúwo jùlọ. Baba mi nà yín pẹ̀lú pàṣán; Èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèé.”
15. Bẹ́ẹ̀ ni ọba kò sì tẹ́tísi àwọn ènìyàn, nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni. Láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ tí a ti sọ fún Jéróbóámù ọmọ Nébátì nípasẹ̀ Áhíjà ará Ṣilò.
16. Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì rí i wí pé ọba kọ̀ láti gbọ́ ti wọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn wí pé:“Ìpín kí ní a ní nínú Dáfídì,ìní wo ni a ní nínú ọmọ Jésè?Ẹ lọ sí àgọ́ yín, ìwọ Ísírẹ́lì!Bojútó ilé rẹ, ìwọ Dáfídì!”Bẹ́ẹ̀ ní gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí ilé wọn.
17. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ń gbé ní ìlú Júdà, Réhóbóámù pàpà ń jọba lórí wọn.