1 Sámúẹ́lì 27:3-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Dáfídì sì bá Ákíṣì jókòó ní Gátì, òun, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ, olúkúlùkù wọn pẹ̀lú ará ilé rẹ̀; Dáfídì pẹ̀lú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, Áhínóámù ara Jésréélì, àti Ábígáílì ará Kámẹ́lì aya Nábálì.

4. A sì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù pé, Dáfídì sá lọ si Gátì: òun kò sì tún wá á kiri mọ́.

5. Dáfídì sì wí fún Ákíṣì pé, “Bí ó bá jẹ́ pé èmi rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ̀, jẹ́ kí wọn ó fún mi ní ibìkan nínú àwọn ìletò wọ̀nyí; èmi yóò máa gbé ibẹ̀: èéṣé tí ìránṣẹ́ rẹ yóò sì máa bá ọ gbé ní ìlú ọba.”

6. Ákíṣì sí fi Síkílágì fún un ní ijọ́ náà nítorí náà ni Síkílágì fí dí ọba Júdà títí ó fí dì òní yìí.

7. Iye ọjọ́ tí Dáfídì fi jókòó ní ìlú àwọn Fílístínì sì jẹ́ ọdún kan àti oṣù mẹ́rin

8. Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì gbé ogun ti àwọn ará Gésúrì, àti àwọn ara Gésírà, àti àwọn ará Ámálékì àwọn wọ̀nyí ni ó sì tí ń gbé ní ilẹ̀ náà, láti ìgbà àtijọ́, bí ó ti fẹ̀ lọ sí Ṣúrì títí ó fí dé ilẹ̀ Éjíbítì.

1 Sámúẹ́lì 27