1 Sámúẹ́lì 24:8-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Dáfídì sì dìde lẹ́yìn náà, ó sì jáde kúrò nínú ihò náà ó sì kọ sí Ṣọ́ọ̀lù pé, “Olúwa mi, ọba!” Ṣọ́ọ̀lù sì wo ẹ̀yìn rẹ̀. Dáfídì sì dojú rẹ́ bọ ilẹ̀ ó sì tẹríba fún un.

9. Dáfídì sì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Èé ha ti ṣe tí ìwọ fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn pé, ‘Wò ó, Dáfídì ń wa ẹ̀mí rẹ́’?

10. Wò ó, ojú rẹ́ ríi lónìí, bí Olúwa ti fi ìwọ lé mi lọ́wọ́ lónìí nínú ihò; àwọn kan ní kí èmi ó pa ọ; ṣùgbọ́n èmi dá ọ sí; ‘Èmi sì wí pé, èmi kì yóò nawọ́ mi sí olúwa mi, nítorí pé ẹni-àmì-òróró Olúwa ni òun jẹ́.’

11. Pẹ̀lúpẹ̀lú, baba mi, wò ó, àní wo etí aṣọ rẹ lọ́wọ́ mi; nítorí èmi gé etí aṣọ rẹ, èmi kò sì pa ọ́, sì wò ó, kí o sì mọ̀ pé kò sí ibi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ mi, èmi kò sì ṣẹ̀ ọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ ń dọdẹ ẹ̀mi mi láti gbà á.

12. Kí Olúwa ṣe ìdájọ́ láàrin èmi àti ìwọ, àti kí Olúwa ó gbẹ̀san mi lára rẹ; ṣùgbọ́n, ọwọ́ mi kì yóò sí lara rẹ.

13. Gẹ́gẹ́ bí òwe ìgbà àtijọ́ ti wí, ìwá-búburú a máa ti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn búburú jáde wá; ṣùgbọ́n ọwọ́ mi kì yóò sí lára rẹ.

1 Sámúẹ́lì 24