1 Sámúẹ́lì 24:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Dáfídì sì fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọn dìde sí Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù sì dìde kúrò ní ihò náà, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.

8. Dáfídì sì dìde lẹ́yìn náà, ó sì jáde kúrò nínú ihò náà ó sì kọ sí Ṣọ́ọ̀lù pé, “Olúwa mi, ọba!” Ṣọ́ọ̀lù sì wo ẹ̀yìn rẹ̀. Dáfídì sì dojú rẹ́ bọ ilẹ̀ ó sì tẹríba fún un.

9. Dáfídì sì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Èé ha ti ṣe tí ìwọ fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn pé, ‘Wò ó, Dáfídì ń wa ẹ̀mí rẹ́’?

10. Wò ó, ojú rẹ́ ríi lónìí, bí Olúwa ti fi ìwọ lé mi lọ́wọ́ lónìí nínú ihò; àwọn kan ní kí èmi ó pa ọ; ṣùgbọ́n èmi dá ọ sí; ‘Èmi sì wí pé, èmi kì yóò nawọ́ mi sí olúwa mi, nítorí pé ẹni-àmì-òróró Olúwa ni òun jẹ́.’

11. Pẹ̀lúpẹ̀lú, baba mi, wò ó, àní wo etí aṣọ rẹ lọ́wọ́ mi; nítorí èmi gé etí aṣọ rẹ, èmi kò sì pa ọ́, sì wò ó, kí o sì mọ̀ pé kò sí ibi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ mi, èmi kò sì ṣẹ̀ ọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ ń dọdẹ ẹ̀mi mi láti gbà á.

12. Kí Olúwa ṣe ìdájọ́ láàrin èmi àti ìwọ, àti kí Olúwa ó gbẹ̀san mi lára rẹ; ṣùgbọ́n, ọwọ́ mi kì yóò sí lara rẹ.

1 Sámúẹ́lì 24