1 Sámúẹ́lì 24:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù padà kúrò lẹ́yìn àwọn Fílístínì a sì sọ fún un pé, “Wò ó, Dáfídì ń bẹ́ ni ihà Éńgédì.”

2. Ṣọ́ọ̀lù sì mú ẹgbẹ̀ẹ́dógún akọni ọkùnrin tí a yàn nínú gbogbo Ísírẹ́lì ó sì lọ láti wá Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ lorí òkúta àwọn ewúrẹ́ igbó.

3. Ó sì dé ibi àwọn agbo àgùntàn tí ó wà ní ọ̀nà, ihò kan sì wà níbẹ̀, Ṣọ́ọ̀lù sì wọ inú rẹ̀ lọ láti bo ẹṣẹ̀ rẹ̀, Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń bẹ lẹ́bàá ihò náà.

4. Àwọn ọmọkùnrin Dáfídì sì wí fún un pé, “Wò ó, èyí ni ọjọ́ náà tí Olúwa wí fún ọ pé, ‘Wò ó, èmi fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́, ìwọ ó sì ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ lójú rẹ.’ ” Dáfídì sì dìde, ó sì yọ́ lọ gé etí aṣọ Ṣọ́ọ̀lù.

5. Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, àyà já Dáfídì nítorí tí ó gé etí aṣọ Ṣọ́ọ̀lù.

6. Òun sì wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Èèwọ̀ ni fún mi láti ọdọ Olúwa wá bí èmi bá ṣe nǹkan yìí sí ẹni tí a ti fi àmì òróró Olúwa yàn, láti nawọ́ mi sí i, nítorí pé ẹni-àmì-òróró Olúwa ni.”

7. Dáfídì sì fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọn dìde sí Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù sì dìde kúrò ní ihò náà, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.

1 Sámúẹ́lì 24