1 Sámúẹ́lì 18:14-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Nínú ohun tí ó bá ṣe, ó ń ní àṣeyọrí ńlá, nítorí tí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.

15. Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù rí bi àṣeyọrí rẹ̀ ti tó, ó sì bẹ̀rù rẹ̀.

16. Ṣùgbọ́n gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà ni wọ́n fẹ́ràn Dáfídì, nítorí ó darí wọn ní ìgbòkègbodò ogun wọn.

17. Ṣọ́ọ̀lù wí fún Dáfídì pé, “Èyí ni àgbà nínú àwọn ọmọbìnrin mi Mérábù. Èmi yóò fi òun fún ọ ní aya. Kí ìwọ sìn mí bí akọni, kí o sì máa ja ogun Olúwa.” Nítorí tí Ṣọ́ọ̀lù wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò gbé ọwọ́ mi sókè síi. Jẹ́ kí àwọn Fílístínì ṣe èyí.”

1 Sámúẹ́lì 18