“Èmi káànú gidigidi pé mo fi Ṣọ́ọ̀lù jọba, nítorí pé ó ti yípadà kúrò lẹ́yìn mi, kò sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́.” Inú Sámúẹ́lì sì bàjẹ́ gidigidi, ó sì képe Olúwa ní gbogbo òru náà.