1 Ọba 8:55-60 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

55. Ó sì dìde dúró ó sì fi ohùn rara súre fún gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì wí pé:

56. “Ìbùkún ni fún Olúwa tí ó ti fi ìsinmi fún Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ̀ bí ó ti ṣèlérí. Kò sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ìlérí rere tí ó ti ṣe láti ọwọ́ Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀ wá.

57. Kí Olúwa Ọlọ́run wa kí ó wà pẹ̀lú wa bí ó ti wà pẹ̀lú àwọn baba wa; kí ó má sì ṣe fi wá sílẹ̀ tàbí kọ̀ wá sílẹ̀.

58. Kí ó fa ọkàn wa sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀, láti máa rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, àti àṣẹ rẹ̀, àti ìlànà rẹ̀, tí ó ti pàṣẹ fún àwọn bàbá wa.

59. Àti kí ó sì jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí, tí mo ti gbà ní àdúrà níwájú Olúwa, kí ó wà nítòsí Olúwa Ọlọ́run wa ní ọ̀sán àti ní òru, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró àti ọ̀rọ̀ Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àìní wa ojoojúmọ́,

60. kí gbogbo ènìyàn ayé lè mọ̀ pé Olúwa òun ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn.

1 Ọba 8